Ìjàpá àti Ajá
Ìjàpá o̩ló̩gbó̩n è̩wé̩ o̩ko̩ Yáníbo àti Ajá jé̩ ò̩ré̩ tímó̩tímó̩.
Ní o̩jó̩ kan, Ìjàpá ati Ajá lo̩ ja olè ni òòru ò̩gànján,
Ìjàpá jí isu ogún, Ajá jí isu mé̩fà,
Bí wó̩n se ńsálo̩ ló̩nà ní agogo méjì òru
Àgbè̩ tí ó ni oko rí wo̩n ó sì bè̩rè̩sí ńsáré tè̩lé wo̩n.
Ajá ju máàrún nínú isu rè̩ so̩nù,
Ìjàpá kò̩ láti ju díè̩ sílè̩ nínú isu rè̩.
Ajá ńsáré lo̩ níwájú, Ìjàpá kò lè sáré
Ìjàpá bá bè̩rè̩sí ko̩ orin wípé:
Ìjàpá: Ajá dúró ran mí le̩rù ) x2
Olùgbè: Fe̩e̩re̩kúfe̩ )
Ìjàpá: Bí o kò bá ràn mí le̩rù màá kígbe olóko á gbó̩
Olùgbè: Fe̩e̩re̩kúfe̩
Ìjàpá: Á gbó̩ ò, a kó wa dè
Olùgbè: Fe̩e̩re̩kúfe̩
Ìjàpá: Á kó wa dè á gbà wá nísu
Olùgbè: Fe̩e̩re̩kúfe̩
Ajá ko da Ìjàpá lóhùn, aja tesè̩mó̩rìn o nsáré lo̩
Okan nínú isu Ijapa bo sile, Ìjàpá si duro lati mú isu yi
Bi Ìjàpá ti ńtú isu rè̩ dì ni olóko dé
Olóko yi si mú Ìjàpá padà wa sí abúlé rè̩
Ó de Ìjàpá lókùn mó̩lè̩ títí di àárò̩ o̩jó̩ kejì.
Ajá ti fesè̩ ho̩, o ti délé.
Ìbéèrè
Oókan. Kíni a ńpe àwo̩n ò̩rò̩ wò̩nyí ni èdè gè̩é̩sì
a. Ìjàpá b. Ajá d. ogún e. àárò̩ e. ò̩ré̩ tímó̩tímó̩ f. méjì g. o̩ko̩
Eéjì. Irú ìwà wo ni Ajá àti Ìjàpá hù yi nípa lílo̩ sí oko olóko?
E̩é̩ta: Kíni a ńpe ni ojú kòkòrò ni ède gè̩é̩sì.
E̩é̩rin: Kíni orùko̩ ìyàwó Ìjàpá?
E̩ fi ìdáhùn yín ránsé̩ sí: This email address is being protected from spambots. You need JavaScript enabled to view it.