Wednesday, 25 December 2024

Atupa

Atupa (Weird but true!!.) A narration of weird but through stories in Yoruba Language.

×

Warning

JUser: :_load: Unable to load user with ID: 526

Bàbàláwo Mò Wá Bè̩Bè̩

Ìjàpá jé̩ o̩ló̩gbó̩n è̩wé̩, olójúkòkòrò, aláìníté̩ló̩rùn ati gbogbo oran lo da lori alábahun

Ìjàpá je o̩ko̩ Yáníbo, lehin osù meje ti Ìjàpá àti Yáníbo fe ara won sile won ko tete bimo

Ni ojo kan, Ìjàpá to Babaláwo lo, o si so fun Babaláwo wipe oun fe se oògùn ti iyawo oun Yáníbo, le fi tete ni oyun. Babaláwo ba se o̩bè̩ ti o ni opolopo efo ati eran ninu, o gbe fun Ìjàpá. Babaláwo si se ikilo fun Ìjàpá wipe, ‘’Iwo Ìjàpá gbodo je ninu o̩bè̩ oògùn naa, Yáníbo, nikan ni o ni lati je o̩bè̩ oògùn naa ko si ayipada nitori igbehin tito o̩bè̩ yi wo ko dara o, ko si si atunse o”. Ìjàpá dupe lowo Babaláwo yi o si pè̩hìndà lati maa lo, Babaláwo tun ran Ìjàpá leti wipe Ko gbó̩dò̩ je ninu o̩bè̩ oògùn naa, ko da ko gbó̩dò̩ towò̩, Ìjàpá si so wipe oun gbo ati pe oun ko ni to ninu o̩bè̩ oògùn yi.

Bí Ìjàpá s̩e ńlo̩ ló̩nà, ó ńgbó̩ ti òórùn o̩bè̩ oògùn náà ńta sánsán. Nígbàtí Ìjàpá rin ibùsò̩ mé̩ta, ara rè̩ kò gbáá mó̩. Ó ro̩ra bó̩ si ibi kò̩rò̩ kan, ó síi wò, ó rí ò̩pò̩ló̩pò̩ e̩ran ìgbé̩, ìgbín, è̩fó̩, e̩ja, gbogbo rè̩ ńta sánsán. Ìjàpá ní Káì o̩bè̩ rèé! Bayi ni Ìjàpá se joko si ìdí igi kan tí a ńpè ní igi o̩sàn àgbálùmò̩, ti Ìjàpá je̩ gbogbo o̩bè̩ na tan pátápátá-porogodo. Ko pe pupo ti Ìjàpá je o̩bè̩ yi tan ni ikun re beeresi ga, iku Ìjàpá bè̩rè̩sí ńtóbi bi ti aboyún.

Ìjàpá kòlè dìde níbití o jóòkó sí ní abé̩ igi o̩sàn, è̩rù bàá, ó bá mura o pada si

ò̩do̩ Babaláwo ti o s̩e oògùn yi, nígbàtí ó de e̩nu ò̩nà ilé Babaláwo, kò le wo̩lé, Ìjàpá ki e̩nu bo̩ orin:

Ìjàpá: Babaláwo mo wa bè̩bè̩
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá Ògùn to se fun mi lè̩kan
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Gbongbo lo yo̩ mi lese
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá Oògùn to se fun mi lo daanu
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Mo fo̩wó̩ kan o̩bè̩ mo fi kenu
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Mo fo̩wó̩ keran mo fi sé̩nu
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Mo boju wokùn o ri gbendun
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Gbogbo e̩sè̩ ló wúwo
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Àìgbó̩ràn ma lo pami o
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá Nko ni hu iwa yi mo o.
Olùgbè: Alugbinrin

Ìjàpá: Babaláwo mo wa bè̩bè̩
Olùgbè: Alugbinrin

Babaláwo ba jade si Ìjàpá, o ni “págà, Ìjàpá sebi mo so fún o, mo kilò̩ fun o wipe o ko gbodo je̩ ninu o̩bè̩ yi”, Babaláwo si so fun Ìjàpá wipe ko si è̩rò̩ re o, è̩rò̩ re ni ò̩run alákeji. Ìjàpá sunkún, o bè̩bè̩ sugbon ko si è̩rò̩ fun. Bayi ni ikùn Ìjàpá wú titi o fi bé̩ ti ìfun, è̩dò̩, ati gbogbo inu Ìjàpá bé̩ si ode ti Ìjàpá si kú.

News Letter

Subscribe our Email News Letter to get Instant Update at anytime

About Oases News

OASES News is a News Agency with the central idea of diseminating credible, evidence-based, impeccable news and activities without stripping all technicalities involved in news reporting.